
By Tokunbo Dada
Cristiano Aviero dos Santos Ronaldo, ọ̀kanlọmọ ti orílẹ̀dè Portugal, òkìnàkíná tí ń tojú oní-ǹkan kìí síná… ẹṣin lọmọ. Lánàá, Ronaldo, ọmọ ogóòjì ọdún, kó àwọn ìsọ̀gbè rẹ̀ yókù mọ́ra láti dáná ìyà sí ìdí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Spain, nínú àṣekágbá ìdíje European Nations League, 2024/2025. Àwọn ènìyàn ti ń wòye tẹ́lẹ̀ wípé Yamal, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, yíò da Portugal l’ágbo nù, Ṣùgbọ́n, Ronaldo fi ye pé tí ọmọdé bá la’sọ bí àgbà, kò lè ní àkísà bí àgbà. Kódà Yamal kò lè mí. Ó dákẹ́ bí ọmọ tí sọjà yọ ibọn sí ní.
Ronaldo gbà àyò kan wọnú àwọ̀n, ìkẹjọ rẹ̀ nínú ìdíje ọ̀hún. Ìṣọwọ́ gbá bọ́ọ̀lù Ronaldo ta lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ gẹ́, tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fi gbóríyìn fún, bó tilè jẹ́ pé Nuno Mendes, ọmọ Portugal, ló ta lẹ́nu jùlọ nínú ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ ọhún. Àsẹ̀yìnwá, àsẹ̀yìnbọ̀, Portugal padà fi Pẹnáritì gbojú Spain mọ́lẹ̀ ni.
